Awon Ohun Ti Egbe Wa Fun Ati Ipetepero Wa

 Our Aims And Objectives

To promote the speaking of Yoruba language amongst Yoruba people, especially our children who are totally losing both the language and culture.

Lati gbe ede Yoruba laruge laarin awon omo Yoruba, paapa awon omo wa ti won nso ede ati asa nu patapata.

To cherish, uphold and project the honour and dignity of Yoruba culture, language and tradition in the United Kingdom.

Lati mojuto igbega ati bu ola ati iyi fun ede ati aṣa Yoruba kaakiri Ilu Gẹẹsi.

To promote full access to education about Yoruba language to all and sundry through media and the use of Information Technology.

Lati gbe eto kikun si eto ẹkọ nipa ede Yoruba fun gbogbo eniyan nipasẹ awọn oniroyin ati lilo Imọ ẹrọ Alaye.

To liase with the Nigerian Federal and State Governments, Nigerian High Commission Office in the UK, educational planners, foreign governments and international organisations on issues connected to Yoruba Language.

Lati ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ati awọn ijọba ipinlẹ, Ọfiisi Ile-iṣẹ giga Naijiria ni ilu Geesi, awọn oluṣeto eto ẹkọ, awọn ijọba ajeji ati awọn ajọ agbaye lori awọn ọran ti o sopọ mọ Èdè Yorùbá.

To work with other organisations inside and outside the United Kingdom to promote Yoruba Language and culture.

Lati sise papo pelu awon ajo miran ninu ati lode ni ilu Geesi lati gbe ede ati asa Yoruba laruge.

Subject to approval by members of the Executive Committee of the Association, to obtain or accept subscriptions, donations, grants, gifts, devices and bequests from individuals, corporations and institutions in furtherance of the Association’s aims and objectives.

Oro wonyi da lori ifọwọsi awọn Igbimọ Alase ti Egbe, lati wa, tabi gba idawo sinu apo egbe, awọn ẹbun owo, awọn ẹbun inawosi, awọn ẹbun ife, awọn ebun ohun elo ati awọn ẹbun lati ọdọ awọn eniyan kọọkan tabi awọn ile iṣẹ orisirisi fun ilosiwaju Egbe ninu ero ati ipetepero Ẹgbẹ.

To organise classes for Yoruba youths in the United Kingdom. To set up a Yoruba Cultural Centre where the aims and objectives of this Association would be further promoted within the United Kingdom

Lati ṣeto awọn kilasi Yoruba fun awọn ọdọ Yoruba ni Ilu Gẹẹsi. Lati ṣeto Ile-iṣẹ Asa Ilu Yoruba nibiti awọn ipinnu ati awọn ibi tafẹde ti Ẹgbẹ yii yoo jẹ igbega siwaju laarin Ilu Gẹẹsi.

To publish a periodic Yoruba Newsletter and other publications to promote the aims and objectives of the Association.

Lati ṣe atẹjade Iwe Iroyin Yoruba nigba kọọkan ati awọn atẹjade miran lati ṣe agbega awọn ero ati awọn ipinnu Ẹgbẹ.

To liase with educational institutions and local authorities in the United Kingdom towards achieving the aims of the Association

Lati ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn ile-ẹkọ ati awọn alaṣẹ agbegbe ni ilu Geesi fun iyọrisi rere ipetepero ti Ẹgbẹ.

To undertake any other activities which are consistent with or which the Association considers will promote its interests, aims and objectives.

Lati ṣe awọn iṣẹ miran ti o ni ibamu pẹlu tabi eyi ti Ẹgbẹ ṣe akiyesi pe yio ṣe agbega awọn ifokansi, awọn ipetepero ati awọn ibi t’afẹde.

Ede Eni, Ni Aami Eni